1. EMI Mimo, ‘Dada orun,
Wa li agbara Re;
K’ o da ina ife mimo,
Si okan tutu wa.
2. Wo, b’ a ti nrapala nihin,
T’ a fe ohun asan;
Okan wa ko le fo k’ o lo,
K’ o de ‘b’ ayo titi.
3. Oluwa ao ha wa titi
Ni kiku osi yi?
Ife wa tutu be si O,
Tire tobi si wa.
4. Emi Mimo ‘Dada orun,
Wa li agbara Re;
Wa da ‘na ‘fe Olugbala
Tiwa o si gbina.
(Visited 523 times, 1 visits today)