1. EMI orun, gb’ adura wa,
Wa gbe ‘nu ile yi,
Sokale pel’ agbara Re,
Wa, Emi Mimo wa.
2. Wa b’ imole, si fihan wa
B’ aini wa ti po to:
Wa, to wa si ona iye,
Ti olododo nrin.
3. Wa bi ina ebo mimo:
S’ okan wa di mimo;
Je ki okan wa je ore,
F’ oruko Oluwa.
4. Wa bi iri, si wa bukun
Akoko mimo yi:
Ki okan alaileso wa
Le yo l’ agbara Re
5. Wa bi adada, n’apa Re,
Apa ife mimo yi:
Wa je ki ijo Re l’ aiye,
Dabi ijo t’ orun.
6. Emi orun, gb’ adura wa,
S’ aiye yi d’ ile Re;
Sokale pel’ agbara Re,
Wa, Emi Mimo wa.
(Visited 4,622 times, 19 visits today)