1. A F’ iyin aiku fun
‘Fe Olorun Baba,
Fun itunu t’ aiye,
At’ ireti t’ orun:
O ran ‘Mo Re aiyeraiye
Lati ku fun ese t’ a da.
2. T’ Olorun Omo ni
Ogo lailai pelu,
T’ o f’ eje Re ra wa
N’nu egbe ainipekun :
O ye, O joba nisiyi,
O si nri eso iya Re.
3. Wole fun oruko,
Olorun emi lai,
Enit’ agbara Re
So elese d’ aye:
On l’ o par’ ise ‘gbala wa,
L’ o si f’ ayo orun k’ okan.
4. ‘Wo Olodumare,
L’ ola ye titi lai,
Eni Metalokan,
T’ O tobi, t’ O l’ ogo:
Nibiti ipa ero pin,
‘Gbagbo bori, ife sin yin.
(Visited 231 times, 1 visits today)