YBH 160

OLORUN ti fi Jesu se

1. OLORUN ti fi Jesu se
Etutu fun ese;
On na l’ okan mi duro ti,
Ninu igbagbo mi,

2. Olorun si ni iyonu
Si eje Omo Re;
Omo si ti mu eje na
Wo ibi mimo lo.

3. Nibe ni eje ibuwon
Nsoro rere fun wa:
Nibe ni turari didun
Ti Alufa nla wa.

4. Angeli now, enu ya won;
Nwon si nteri won ba
Nitori anu Olorun
T’ o f’ eje gba ni la.

5. Emi o ma fi igbagbo
Sunmo ‘bi mimo yi;
Ngo ma ko’ rin s’ Olugbala
Ngo be k’ O gb’ okan mi.

6. A ya orin mi si mimo,
Nipa eje Re na;
O si dun nipa igbgbo
O je ‘towo orun.

(Visited 204 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you