YBH 161

OLUWA, alaimo l’ emi

1. OLUWA, alaimo l’ emi,
Ninu ese l’ a gbe bi mi,
Eniti mo se lara re
L’ o fi ese ba aiye je.

2. Lojukanna bi a ti mi,
Eso ese nru fun iku;
Ofin bere okan pipe;
Sugbon ara wa dibaje.

3. Mo wole ni iwaju Re;
Ore Re nikan l’ abo mi:
Ko si asa t’ o le we mi,
Inu ni egbin nag be wa.

4. Olugbala mi, eje Re
Nikan l’ o le se etutu;
L’ o le mu mi fun bi yinyin:
Ipa enia ko le se.

5. ‘Gbati ese eyo mi l’ enu,
Okan mi ko le n’ isimi;
Je ki ngb’ ohun ‘dariji Re,
K’o mu egun mi rirun yo.

(Visited 117 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you