1. ENI ‘subu se le
Mo loju Olorun,
Bi O ba tele pipe wa
Ao subu lab’ egbe.
2. Bi O ba fi oju
Mimo be ‘wa wa wo,,
A ha le ri awawi fun
Eyo ese kanso?
3. Oke, n’ ibinu Re,
Ko ibujoko won,
Aiye wariri, o s’ ipo,
Awon opo re ye.
4. Bawo l’ eni ‘subu
Se b’ Olorun ro ‘jo?
Ko s’ enit o le ko loju,
Laisi eje Jesu.
(Visited 97 times, 1 visits today)