1. OLUWA, bawo l’ okan mi
Ti bale lekan ri;
Mo wa laye laisi ofin,
Mo seb’ ese mi ku.
2. Ireti duro sinsin,
Sugbon nigb’ ofin de,
Pelu imole t’ o n’ ipa,
Mo ri alaiye mi.
3. Ebi mi ko han tobi ri,
Ki nto f’ iberu ri,
Bi ofin Re ti to, t’ o pe,
T’ o si je mimo to.
4. ‘Gbana l’eru pa okan mi,
Ese mi tun soji,
Mo ti bi Olorun ninu,
Ireti mi si ku.
5. Olorun, mo nke lais’ are
Fun ipa igbala;
Ja ajaga ese kuro,
K’ O da eru n’ ide.
(Visited 158 times, 1 visits today)