1. NIBO n’ isimi wa
Fun okan alare?
Asan ni lati w’ aiye ka,
Lati wa ‘le okun.
2. Aiye ko le fun ni
Layo t’ a nkedun fun;
Igba ko tan aiyeraiye,
Iku ko pin nihin.
3. Aiye kan wa loke,
Lehin tie kun yi,
Ti a ki fi odun d’ iwon,
Gbogbo re je ife.
4. Iku kan mbe, b’ a ku
T’ oro re ko duro:
A! eru ailopin t’o wa
Yi iku ‘keji ka.
5. Oluwa, jo ko wa
Lati sa fun ‘ku na:
K’ a ma ba le wa lodo Re,
A si segbe lailai.
(Visited 136 times, 1 visits today)