1. ELESE kil’ o ni t’ o
Jo ayo onigbagbo?
Pelu ododo riro,
Ona re dun to ti ‘wa
2. Onisegun t’ o daju
Ha ntele o l’ ona re,
Ti mb’ ororo s’ ogbe re,
Gb’ egun oloro gun o?
3. Gbat’ iji ba nku loke,
O ha ni abo sibe?
Ipoka re ha le mu,
Olugbala sunmo o?
4. O le t’ ona sisu na
Laifoya, lojo nla ni?
O le so t’ ebo t’ a ru?
Fo lat’ aiye lo s’ orun?
(Visited 302 times, 1 visits today)