1. “A YE si mbe!” ile Odagutan,
Ewa ogo re npe o pe, “Ma bo”,
Wole, wole, wole nisisiyi.
2. Ojo lo tan, orun si fere wo,
Okunkun de tan, ‘mole nkoja lo;
Wole, wole, wole nisisiyi.
3. Ile iyawo na kun fun ase!
Wole, wole to Oko-‘yawo lo:
Wole, wole, wole nisisiyi.
4. “Aye si mbe!” ilekun si sile,
Ilekun ife: iwo kop e ju,
Wole, wole, wole nisisiyi.
5. Wole! Wole! Tire ni ase na,
Wa gb’ ebun ‘fe aiyeraye l’ ofe!
Wole, wole, wole nisisiyi.
6. Kiki ayo l’o wa nibe; wole!
Awon angeli npe o fun ade;
Wole, wole, wole nisisiyi.
7. L’ ohun rara n’ ipe ife na ndun!
Wa, ma jafara, wole ase na,
Wole, wole, wole nisisiyi.
8. O nkun, o nkun! Ile ayo na nkun!
Yara! Mase pe, ko kun ju fun o,
Wole, wole, wole nisisiyi.
9. K’ ile to su ilekun na le ti!
‘Gbana, o k’abamo! “Ose! Ose!”
Ose! Ose! ko s’aye mo, ose!