YBH 171

ELESE, o ha gan ise

1. ELESE, o ha gan ise
T’ a f’ anu ran lat’ oke
Ohun jeje l’ O fi ranse,
Oro Re kun fun ife;
Te ‘ti lele,
Ise Re kun fun ife.

2. Gbo awon ojise rere,
Nwon nj’ ise Oba Sion;
“Idariji fun elese
L’ ofe, l’ oruko Jesu,”
B’ o ti po to,
‘Dariji l’ oruko Re.

3. F’ okan itanje at’ eru,
Nwon mu ‘bale aiya wa,
Nwon wa fi ise itunu,
Le omije nyin kuro;
Ojise ‘re,
Nu omije nu kuro.

4. Tani ti gba ihin wa gbo?
Tani gb’ oro ayo na?
T’ o gba ihin ‘dariji mu,
Ti Oluwa na si yin?
E ha le gan
Ore, anu Oluwa.

(Visited 255 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you