YBH 172

ESE ti e ko le sailo

1. ESE ti e ko le sailo
Emi nyin danu lor’ asan,
Ti ohun kanso, na t’ o ye,
Ko si n’nu gbogbo ero nyin?

2. Olorun npe lat’ oke wa,
Jesu nfi ‘fe iku Re ro,
Okan ebi ko ye yonu,
Gbogbo re yio ha lo lasan?

3. Bayi, k’ oju re yio ma ri
Ohun t’o gb’ okan re titi;
Beko, l’ aiyeraiye yio ri,
Gbat’ akoko iku ba de.

4. Olorun fun ni l’ ore Re
F’ imole si okan gbogbo,
K’ a ma lo emi t’ O dasi,
Danu lori ohun asan.

(Visited 190 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you