1. MURA elese lati gbon,
Ma duro de ojo ola;
Niwon b’ o ti kegan ogbon,
Be l’ o si soro lati ri.
2. Mura lati bere anu,
Ma duro de ojo ola;
Ki igba re ko ma ba tan,
Ki ojo ale yi to tan.
3. Mura, elese, k’ o pada,
Ma duro de ojo ola;
Nitori k’ egun ma be o,
K’ ojo ola k’ o to bere.
4. Mura lati gba ibukun,
Ma duro de ojo ola;
Ki fitila re ma ba ku,
K’ ise rere re to bere.
5. Oluwa, y’ elese pada,
Ji kuro ninu were re;
Ma je k’ o tapa s’ imo Re,
K’ o ma f’ egbe re se ‘lora.
(Visited 294 times, 1 visits today)