1. ELESE e yi pada,
Ese ti e o fi ku?
Eleda nyin ni nbere;
T’ O fe ki e ba On gbe:
Oran nla ni O mbi nyin,
Ise owo Re ni nyin,
A! enyin alailope,
Ese t’e o ko, ‘fe Re.
2. Elese e yi pada,
Ese ti e o fi ku?
Olugbala ni mbere,
Enit’ o gb’ emi nyin la;
Iku Re y’o j’ asan bi?
E o tun kan mo ‘gi bi?
Eni ‘rapada, ese
Tie o gan ore Re?
3. Elese e yi pada
Ese ti e o fi ku?
Emi Mimo ni mbere
Ti nf’ ojo Gbogbo ro nyin
E ki o ha gb’ ore Re?
E o ko iye sibe?
A ti nwa nyin pe, ese
T’ e mbi Olorun ninu?
4. Iyemeji ha nse nyin
Pe ife ni Olorun,
E ki o ha gb’ oro Re?
K’e gba ileri Re gbo?
W’ oluwa nyin l’ odo nyin,
Jesu nsun: w’ omije Re
Eje Re pelu nke pe,
“Ese ti e o fi ku?”
(Visited 2,102 times, 1 visits today)