1. IYE wa ni wiwo, Enit a kan mo ‘gi
Iye wa nisisiyi fun o;
Nje wo O elese k’ o le ri igbala,
Wo Enit’ a kan mo ‘gi fun o.
Refrain
Wo! wo! wo k’ o ye,
Iye wa ni wiwo Enit’a kan mo gi
Iye wa nisisiyi fun o.
2. Kil’ o se ti On fi dabi
Bi a ko gb’ ebi re ru Jesu!
Eje ‘wenumo se san lati iha Re,
B’ iku Re ko j’ etu f’ ese re?
Refrain
Wo! wo! wo k’ o ye,
Iye wa ni wiwo Enit’a kan mo gi
Iye wa nisisiyi fun o.
3. Ki s’ ekun ‘piwada ati adura re,
Eje na l’ o s’ etutu f’ okan;
Gbe eru ese re lo si odo Eni,
Ti o tit a eje na sile.
Refrain
Wo! wo! wo k’ o ye,
Iye wa ni wiwo Enit’a kan mo gi
Iye wa nisisiyi fun o.
4. Ma siyemeji s’ ohun t’ Olorun wi,
Ko s’ohun t’o ku lati se mo,
Ati pe On yio wa nikehin aiye,
Y’o si s’asepari ise Re.
Refrain
Wo! wo! wo k’ o ye,
Iye wa ni wiwo Enit’a kan mo gi
Iye wa nisisiyi fun o.
5. Nje wa f’ayo gba iye ainipekun,
Ni owo Jesu ti fifun ni;
Si mo daju pe iwo ko si le ku lai,
N’gbati Jesu Ododo re wa.
Refrain
Wo! wo! wo k’ o ye,
Iye wa ni wiwo Enit’a kan mo gi
Iye wa nisisiyi fun o.