YBH 178

OLUWA, sanu, dariji

1. OLUWA, sanu, dariji;
Da okan t’o yipada si;
Ki sip e anu Re tobi
Elese ko le ro mo O?

2. Ese mi po, sugbon ko le
Ju agbara ore Re lo;
Titobi Re ko ni opin,
Be ge ni k’a ri ife Re.

3. We ese kuro l’okan mi,
Si mu okan ebi mi mo;
L’okan mi ni eru na wa,
Ese ehin ro mi loju.

4. Ete mi f’ itiju jewo
Ese s’ ofin at’ ore Re
Bi idajo Re yio ba le,
Mo j’ ebi, are ni Tire.

5. B’ idajo kankan gb’ emi mi,
L’ oju ‘ku ngo da O l’ are,
B’ a si ran mi lo s’ iparun
Tito ni l’ oju ofin Re.

6. Sibe, gba elese t’ o ngbon,
Ti ireti re nra baba,
Bi o le r’ ileri didun
Lati ba le n’nu oro Re.

(Visited 261 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you