YBH 185

ALAIMO lie mi

1. ALAIMO lie mi,
Olorun Oluwa!
Emi ha gbodo sunmo O
T’ emi t’ eru ese?

2. Eru ese yii npa
Okan buburu mi;
Yio ha si ti buru to,
L’ oju Re mimo ni!

3. Emi o ha si ku
Ni alainireti
Mo r’ ayo ninu iku Re,
Fun otosi b’ emi.

4. Eje ni ti O ta,
Ti ‘se or-ofe Re,
Le w’ elese t’ o buruju,
Le m’ okan lile ro.

5. Mo wole l’ ese Re,
Jo k’ O dariji mi;
Nihin l’ emi o wa titi
‘Wo o wipe, “Dipe.”

(Visited 1,354 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you