1. IWO low’ Enit’ ire nsan,
Mo gb’ okan mi si O;
N’ ibanuje at’ ise mi,
Oluwa ranti mi.
2. ‘Gba mo kerora l’ okan mi,
Ese wo mi l’ orun;
Dari gbogbo ese ji mi,
Ni ife ranti mi.
3. Idanwo kikan yi mi ka,
O buru, nko le sa;
Oluwa fun mi l’ agbara,
Fun, rere, ranti mi.
4. B’ itiju at’ egan ba wa
L’ oju mi n’tori Re;
Ngo yo s’ egan, ngo gba ‘tiju,
B’ Iwo bar anti mi.
5. Oluwa, ‘gba iku ba de,
Em’ o sa ku dandan;
K’ eyi j’ adua ‘gbehin mi,
Oluwa, ranti mi.
(Visited 1,420 times, 1 visits today)