1. OLUGBALA, gb’ ohun mi,
Gb’ ohun mi, gb’ ohun mi;
Mo wa sodo Re, gba mi,
Nibi agbelebu.
Emi se, sugbon O ku,
Iwo ku, Iwo ku;
Fi anu Re pa mi mo
Nibi agbelebu.
Oluwa, jo gba mi,
Nk’ y’o bi O n’ inu mo!
Alabukun, gba mi
Nibi agbelebu.
2. Bi ngoba tile segbe,
Ngo bebe! Ngo bebe!
Iwo li Ona, Iye
Nibi agbelebu,
Ore-ofe Re t’ a gba,
L’ ofe ni! l’ ofe ni!
F’ oju anu Re wo mi
Nibi agbelebu.
3. F’ eje mimo Re we mi,
Fi we mi! fi we mi!
Ri mi sinu ibu re
Nibi agbelebu.
‘Gbagbo l’o le fun wa ni
‘Dariji! ‘Dariji!
Mo f’ igbagbo ro mo O
Nibi agbelebu.
(Visited 1,637 times, 7 visits today)