1. OLUWA, ma m’ oju kuro
Lodo emi t’ o ny’ ile,
Ti nsokun ese aiye mi,
N’ ite anu ife Re.
2. Ma ba mi lo sinu ‘dajo,
Bi ese mi ti po to:
Nitori mo mo daju pe,
Emi ko wa lail ebi.
3. Iwo mo ki nto jewo re
Bi mo tin se l’ aiye mi,
At’ iwa isisiyi mi
Gbogbo re l’ O kiyesi.
4. Emi ko ni f’ atunwi se,
Ohun ti mo fe toro
Ni iwo mo ki nto bere,
Anu ni l’ opolopo.
5. Anu, Oluwa ni mo fe;
Anu l’ eyi t’ o ye mi;
Anu, Oluwa, je ki nri
Anu nipo ijebi.
(Visited 711 times, 1 visits today)