1. OLUWA, b’ agbowode ni,
Mo gb’ okan mi le O;
Oluwa, f’ ore-ofe wi,
K’ O se anu fun mi.
2. Mo lu aiduro aiya mi,
Ekun at’ irora;
K’ Ogb’ okan mi n’nu irora
K’ Ose anu fun mi.
3. N’ itiju mo jew’ ese mi,
Jo fun mi n’ ireti;
Mo be, ‘tori eje Jesu,
K’ O se anu fun mi.
4. Olori elese ni mi,
Ese mi papoju;
Nitori iku Jesu wa,
K’ O se anu fun mi.
5. Mo duro ti agbelebu,
Nko sa f’ ojiji re;
Ti Olorun t’ o po l’ anu,
O ti sanu fun mi.
(Visited 278 times, 1 visits today)