YBH 191

BABA ma yi oju kuro

1. BABA ma yi oju kuro
Fun emi otosi;
Ti np’ ohunrere ese mi
N’ iwaju ite Re.

2. ‘Lekun anu t’ O si sile
F’ akerora ese,
Ma ti i mo mi Oluwa,
Je ki emi wo ‘le.

3. Emi ko nip e mo njewo,
B’ aiye mi ti ri ri;
Gbogbo re lat’ ehinwa ni
‘Wo mo dajudaju.

4. Mo wa si ‘lekun anu Re,
Nibiti anu po,
Mo fe ‘datiji ese mi,
K’ O mu okan mi da.

5. Emi ko ni tenumo
Itunu ti mba ni;
‘Wo mo, Baba, ki nto bere
Ibukun t’ emi nwa.

6. Anu, Oluwa ni mo fe,
Eyiyi l’ opin na;
Oluwa, anu l’ oye mi,
Jeki anu Re wa.

(Visited 545 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you