1. OLUWA t’ o mo julo,
K’ a wole l’ oruko Re;
Ife Re ki ye titi,
Kab’yesi Oba rere.
2. B’ a ti je alaiye to,
Sibe O ngbo orin wa,
Iyin t’ o ye l’ ao fun O,
Gba ‘ba nkorin n’ite Re.
3. Niwon b’ a ti wa l’ aiye,
To ese wa s’ ona Re,
Titi ao fi ba O gbe,
Ti ao si fi r’ ogo Re.
4. ‘Gbana pelu harpu wa,
Ao m’ orin didun soji,
Ao si gbe ohun wa ga
Ninu orin iyin Re.
(Visited 284 times, 1 visits today)