YBH 20

KO mi Oluwa bi a ti

1. KO mi Oluwa bi a ti
Je gbohungbo oro Re;
B’ O ti wa mi je k’ emi wa,
Awon omo Re t’ o ti nu.

2. To mi Oluwa kin le to
Awon t’ o sako si ona;
Bo mi Oluwa ki nle fi
Manna Re b’ awon t’ ebi npa.

3. Fun mi l’ agbara: fie se
Mi mule lori apata;
Ki nle na owo igbala
S’ awon t’ o nri sinu ese.

4. Ko mi Oluwa kin le fi
Eko rere Re k’ elomi;
K’ oro mi le f’ iye Re fo
De ikoko gbogbo okan.

5. F’ isimi didun Re fun mi,
Ki nle mo b’o ti ye lati
Fi pelepele s’ oro Re
Fun awon ti are ti mu.
Jesu, fie kun Re kun mi,
Fi kun mi li opolopo,
Ki ero ati oro mi,
Kun fun ife at’ iyin Re.

7. Lo mi, Oluwa, an’ emi,
Bi O ti fe nigbakugba;
Titi em’ o fi r’ oju Re,
Pelu ayo ninu ogo.

(Visited 669 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you