1. OLUWA, a wa ‘do, Re,
L’ese Re l’ a kunle si;
A! ma kegan ebe wa,
A o wa O lasan bi?
2. L’ ona ti O yan fun wa,
L’ a nwa O lowolowo;
Oluwa, a ki y’o lo,
Tit’ Iwo y’o bukun wa.
3. Ranse lat’ oro Re wa,
Ti o fi ayo fun wa;
Je ki Emi Re k’ o fun
Okan wa ni igbala.
4. Je k’ a wa k’ a si ri O
Ni Olorun Olore;
W’ alaisan, da ‘gbekun si
Ki gbogbo way o si O.
(Visited 481 times, 2 visits today)