YBH 22

JESU, nib’ eni Re pade

1. JESU, nib’ eni Re pade,
Nibe nwon r’ ite anu Re;
Nibe nwon wa O, nwon ri O,
Ibikibi n’ ile owo.

2. Ko s’ ogiri t’ o se O mo,
O ngbe inu onirele;
Nwon mu O wa ‘gba nwon mbowa,
‘Gba nwon nre ‘le, nwon mu O lo.

3. Olusagutan eni Re,
So anu Re ‘gbani d’otun,
So adun oruko nla Re,
Fun okan ti nwa oju Re.

4. K’ ar’ ipa adura nihin,
Ti y’o fun igbagbo l’okun,
Ti y’o gbe ife wa s’oke,
Ti y’o f’orun siwaju wa.

5. Oluwa, ‘Wo mbe nitosi,
N’ Apa Re, d’ Eti Re sile;
Si orun, sokale Kankan,
Se gbogbo okan in Tire.

(Visited 772 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you