1. MO j’ alejo nihin, ‘nu ile ajeji,
Ile mi jin rere, l’or’ ebute wura;
Lati je iranse n’koja okun l’ohun,
Mo nsise nihin f’ oba mi
Refrain
Eyi ni ‘se ti mo wa je,
‘Se t’ awon angel’ nko l’orun:
E b’Olorun laja l’Oluwa Oba wi,
E ba Olorun nyin laja.
2. Eyi l’ase Oba, k’eniyan n’bi gbogbo
Ronupiwada kuro ninu ‘dekun ese,
Awon t’o ba gboran yio j’oba pelu Re.
Eyi ni ‘se mi f’ Oba mi
Refrain
Eyi ni ‘se ti mo wa je,
‘Se t’ awon angel’ nko l’orun:
E b’Olorun laja l’Oluwa Oba wi,
E ba Olorun nyin laja.
3. Ile mi dara ju petele Saron lo,
Nibiti ‘ye ainpekun at’ ayo wa;
Ki nso fun araiye, bi nwon se lee gbe’be:
Eyi n’ise mi f’ Oba mi.
Refrain
Eyi ni ‘se ti mo wa je,
‘Se t’ awon angel’ nko l’orun:
E b’Olorun laja l’Oluwa Oba wi,
E ba Olorun nyin laja.
(Visited 524 times, 1 visits today)