YBH 196

EWA otosi elese

1. EWA otosi elese,
Wa li akoko anu;
Jesu nduro lati gba nyin,
O kun fun ‘fe at’ ipa;
O le gba nyin,
O fe, ma siyemeji.

2. Ma je k’ ero da nyin duro,
Mase ro pe e ko ye,
Gbogbo yiye ti O fe ni
Pe k’ e ri ailera nyin:
On ni fun ni,
Imole t’ Emi l’ eyi.

3. Pelu ‘rora ninu ogba,
Eleda re dobale;
Wo li ori igi eje,
Gbo igbe Re k’ o to ku:
“O ti par!”
Elese, ‘yi ko ha to?

4. Olorun g’ oke l’ awo wa,
O nfi eje Re bebe;
Fi igboiya sunm’ odo Re;
Mase da okan meji:
Lehin Jesu,
Ko s’ olore f’ elese.

(Visited 316 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you