1. MO fi omije wo yika,
Aiye su bi iji okun;
Sibe, larin re, mo gb’ ohun,
O nwi, je pe, “Wa sodo Mi!”
2. O nso t’ ibi ayo fun mi,
T’ ibit’ okan mi le salo;
Si alare, t’ a nse n’ ise,
Ipe na dun, “Wa sodo Mi!”
3. Wa, ko si ohun t’ o duro
Aiye ki ‘se bi ‘simi re;
Ko oju ekun si orun,
Wa sodo Emi ipin re
4. A! ohun anu, ohun ‘fe,
Ninu ija on ‘banuje,
Ti mi lehin, mu ‘nu mi dun;
Si wi je pe. “Wa sodo Mi!”
(Visited 163 times, 1 visits today)