1. ARE mu o, aiye su o,
Lala po fun o?
Jesu ni, “Wa si odo, Mi,
K’ o simi.”
2. Ami wo l’ emi o fi mo
Pe On l’ O npe mi?
Am’ iso wa lowo ati
Ese Re.
3. O ha ni ade bi oba,
Ti mo le fi mo?
Toto, ade wa l’ ori Re,
T’ egun ni.
4. Bi mo ba ri, bi mo tele,
Kini ere mi?
Opolopo iya ati
‘Banuje.
5. Bi mo tele tit’ aiye mi,
Kini ngo ri gba?
Ekun a d’ opin, o simi
Tit’ aiye.
6. Bi mo bere pe k’o gba mi,
Y’o ko fun mi bi?
B’ orun at’ aiye nkoja lo,
Ko je ko.
7. Bi mo ba ri, ti mo ntele,
Y’o ha bukun mi?
Awon ogun orun nwipe,
Yio se.
(Visited 671 times, 1 visits today)