1. ENYIN omo oku,
T’ o wa ninu ese,
Gb’ ohun ihinrere,
Jesu ranse si iyin.
Enyin ent-egbe, e wa;
Ni apa Jesu, aye mbe.
2. E ma pe titi mo,
Ma wa awawi mo;
O ni k’ e wa loni,
Bi e tile tosi;
Gbogbo nkan seta, ‘lese wa:
Fun gbogbo mbe.
3. Gba oro t’ orun gbo,
Ti onise Re nso;
Alanu l’ Oluwa,
Oto l’ oruko Re;
Okan isubu, pada wa,
S’ aigbekele ‘nu, aye mbe.
4. Enyin t’ ife Re fa,
E sunmo odo Re;
Kristi t’ oke pen yin,
E gb’ ohun didun Re;
Enikeni t’ o fe k’ o wa
Ni aiya anu, aye mbe.
(Visited 361 times, 1 visits today)