YBH 205

JESU npe wa l’ osan, l’ oru

1. JESU npe wa l’ osan, l’ oru
Larin irumi aiye;
Lojojumo l’ a ngb’ ohun Re
Wipe, “Kristian, tele Mi.”

2. Awon Apostili ‘gbani,
Ni odo Galili ni;
Nwon ko ile, ona sile,
Gbogbo nwon si nto lehin.

3. Jesu npe wa larin lala
Aiye wa buburu yi;
Larin Afe aiye, O nwi
Pe, “Kristian, e feran Mi.”

4. Larin ayo at’ ekun wa,
Larin ‘rora on osi,
Tantan L’ O npe l’ ohun rara
Pe, “Kristian, e feran Mi.”

5. Olugbala, nip’ anu Re,
Je ki a gbo ipe Re,
F’ eti ‘gboran fun gbogbo wa,
K’ a fe O ju aiye lo.

(Visited 5,424 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you