1. GBO okan mi, bi Angeli ti nkorin,
Yika orun ati yika aiye;
E gbo bi oro orin won ti dun to!
Ti nso ‘gbati ese ki y’o si mo:
Angeli Jesu, angel’ ‘mole,
Nwon nkorin ayo pade ero l’ ona.
2. B’ a si tin lo, be l’ a si ngbo orin won.
Wa, alare, Jesu l’ O ni k’ e wa;
L’ okunkun ni a ngbo orin didun won,
Ohun orin won ni nf’ ona han wa.
3. Ohun Jesu ni a ngbo l’ ona rere,
Ohun na ndun b’ agogo y’ aiye ka,
Egbegberun awon t’ o gbo ni si mbo:
Mu nwon w’ odo Re, Olugbala wa.
4. Isimi de, lehin ise on are:
Ojumo mo, lehin okun aiye;
Irin ajo pari f’ awon alare,
Nwon si ti d’ orun, ibi isimi.
5. Ma korin nso, enyin Angeli rere,
E ma korin didun k’ a ba ma gbo;
Tit’ ao fi nu omije oju wa nu:
Ti a o si ma yo titi lailai.
(Visited 3,148 times, 3 visits today)