1. “WA sodo Mi, alare
Ngo fun nyin n’ isimi.”
A! ohun didun Jesu,
Ti o p’ elese wa,
O nso ti ore ofe,
Ati t’ Alafia,
Ti ayo ti ko l’opin,
T’ife ti ko le tan.
2. “E wa, enyin omo Mi,
Ngo fun nyin n’ imole.”
A! ohun ife Jesu,
Ti nle okunkun lo;
Awa kun fun ‘banuje,
A ti s’ ona wa nu;
Imole yio m’ ayo wa,
Oro yio m’ orin wa.
3. “E wa, enyin ti ndaku,
Ngo fun nyin ni iye.”
Ohun Alafia Jesu,
T’ o f’ opin s’ ija wa.
Oju ota wa koro,
Ija si le pupo;
Sugbon ‘Wo fun wa n’ ipa,
A bori ota wa.
4. “Enikeni t’o ba wa
Emi ki y’o ta nu.”
A! ohun suru Jesu
T’ o le ‘yemeji lo!
Ninu ife iyanu
T’ o p’ awa elese,
B’ a tile je alaiye
S’ odo Re, Oluwa.
(Visited 438 times, 1 visits today)