1. NIGBAT’ idanwo yi mi ka,
T’ idamu aiye mu mi,
Ti Esu wa bi ore mi,
Lati wa iparun mi.
Oluwa, jo masai pe mi,
B’ O ti p’ Adam n’nu ogba,
Pe, “Nibo l’ owa, elese?”
Ki nle bo ninu egbe.
2. Nigbat’ esu mu ‘tanje re
Gbe mi g’ or’ oke aiye,
T’ o ni ki nteriba fun on
K’ ohun aiye je t’ emi.
3. N’gba bilisi fi tulasi
Fe mu mi y’ ase Re da,
T’ o duro gangan l’ ehin mi,
N’ ileri pe ko si nkan.
4. Nigbati mo ba fe to ‘pa
‘Damoran on ‘fe ‘nu mi,
T’ okan mi nse kilakilo,
Ti nko tutu, nko gbona.
5. Nigbati k s’ alabaro,
T’ olutunu si jina,
T’ ibanuje ja mi gbongbon
Bi iyo ninu okun,
6. Nigba bi aja ti ko gbo
Fere ti olode mo,
Sonu s’ aginju aiye lo,
Latin’ ireti ipada,
7. Nigbati igbekele mi
Di t’ ogun at’ orisa,
T’ ogede di adura mi,
T’ ofo di ajisa mi,
(Visited 1,977 times, 2 visits today)