YBH 210

JESU nigba ‘danwo

1. JESU nigba ‘danwo,
Gbadua fun mi;
K’ emi ma ba se O,
Ki nsi sako lo:
‘Gba mba nsiyemeji,
K’ o bojuwo mi;
K’ eru tab’ isaju,
Ma mu mi subu.

2. B’ aiye ba si nfa mi,
Pelu adun re;
T’ ohun ‘sura aiye
Fe han mi l’ emo:
Jo mu Getsemane
Wa s’ iranti mi,
Tabi irora Re,
L’ oke Kalfari.

3. B’ o bap on mi l’ oju,
Ninu ife Re;
Da ibukun Re le,
Ori ebo na:
Ki nf’ ara mi fun O
Lori pepe Re;
B’ ara ko ago na
Igbagbo y’o mu.

4. ‘Gba mo ban re ‘boji
Sinu ekuru
T’ ogo orun si nko
L’ eti bebe na,
Ngo gbekel’ oto Re,
N’ ijakad’ iku,
Oluwa, gb’ emi mi,
S’ iye ailopin.

(Visited 3,661 times, 2 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you