1. ELESE wa sodo Jesu
Enit’ O wa gba o la
Enit’ O gbe are re wo,
Lati irora re.
Olodumare ni Eni
T’ o fie mi Re fun o;
Orun at’ aiye y’o koja
Sugbon On wa titi lai.
2. Ki ojo aiye re to pin,
K’ iku to p’ oju re de,
Yara, wa Olugbala re,
K’ akoko na to koja,
Gbo b’ ohun Re ti nkepe o,
“Elese wa sodo Mi
Ko eru re na to Mi wa;
Gbagbo, reti ma beru.”
(Visited 1,236 times, 1 visits today)