YBH 212

OKAN mi, sunmo ‘te anu

1. OKAN mi, sunmo ‘te anu,
Nibi Jesu ngb’ ebe,
F’ irele wole l’ ese Re,
‘Wo ko le gbe nibe.

2. Ileri Re ni ebe mi,
Eyi ni mo mu wa;
Iwo npe okan t’ eru npa,
Bi emi, Oluwa.

3. Eru ese wo mi l’ orun,
Esu nse mi n’ ise;
Ogun l’ ode, eru ninu,
Mo wa isimi mi.

4. Se Apata at’ Asa mi,
Ki nfi O se abo;
Ki ndoju ti Olufisun,
Ki nso pe Kristi ku.

5. Ife iyanu! Iwo ku,
Iwo ru itiju;
Ki elese b’ iru emi,
Le be l’ oruko Re.

(Visited 1,893 times, 2 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you