1. LO, l’ oro kutu kutu,
Lo, ni osangangan,
Lo, ni igba asale,
Lo l’ oganjo oru;
Lo, t’ iwo t’ inu rere,
Gbagbe ohun aiye,
Si kunle n’ iyewu re,
Gb’ adura n’ ikoko.
2. Ranti awon t’ o fe o,
At’ awon t’ iwo fe;
Awon t’ o korira re,
Si gb’ adura fun won;
Lehin na, toro ‘bukun,
Fun ‘wo tikalare;
Ninu adura re, ma
Pe oruko Jesu.
3. B’ aye ati gb’ adura
N’ ikoko ko si si,
T’ okan re fe gb’ adura,
‘Gbat’ ore yi o ka:
‘Gbana adura jeje
Lat’ inu okan re
Y’o de odo Olorun,
Olorun Alanu.
4. Ko si ayo kan l’ aiye,
T’ o si ju eyi lo;
Nit’ agbara t’ a fun wa,
Lati ma gb’ adura;
‘Gbat’ inu re ko ba dun,
Je k’ okan re wole;
Ninu ayo re gbogbo,
Ranti Olore re.
(Visited 533 times, 1 visits today)