1. OMO Olorun nlo s’ ogun
Lati gb’ ade Oba:
Opagun Re si nfe, lele,
Tal’ o s’ om-ogun Re?
Enit’ o le mu ago na,
T’ o le bori ‘rora,
T’ o le gbe agbelebu re,
On ni om’-ogun Re.
2. Martir’ ikini t’o ko ku,
O r’ orun si sile;
O ri Oluwa re l’ oke,
O pe, k’ o gba on la;
On ti ri idariji gba;
Ninu ‘rora iku,
O bebe f’ awon t’ o npa lo,
Tani s’ om’-ogun Re?
3. Egbe mimo: awon wonni
T’ Emi Mimo ba le;
Awon akoni mejila,
Ti ko ka iku si:
Nwon f’ aiya ran ida ota,
Nwon ba eranko ja;
Nwon f’ orun won le ‘le fun ‘ku
Tani ns’ om’-ogun re?
4. Egbe ogun t’ agba, t’ ewe
T’ okunrin, t’ obirin,
Nwon y’ ite Olugbala ka,
Nwon wo aso funfun.
Nwon de oke orun giga
N’nu ‘se at’ iponju:
Olorun fun wa l’ agbara
K’ a le s’ om’-ogun Re.
(Visited 439 times, 1 visits today)