YBH 216

OLORUN npe, ngo ha s’ aigbo

1. OLORUN npe, ngo ha s’ aigbo?
Ngo ha s’ afe aiye d’ owon?
Odun y’o ha ma rekoja
K’ okan mi ma togbe sibe?

2. Olorun npe, ngo ha joko?
Mo ha le s’ egan ohun Re?
Fi ese san ike anu?
O npe sibe, ngo ha duro?

3. Olorun npe, yio ha kankun
Ki nt’ ilekun okan pinpin?
O nduro sibe lati gba,
Mo je bi Emi Re ninu?

4. Olorun npe, ngo ha s’ aigbo?
Ki nma gbe ‘nu ide sibe?
Mo duro, sugbon ko ko mi,
O npe sibe, okan mi ji.

5. Olorun npe, nko le duro,
Laipe lo mo jow’ okan mi;
Aiye odigbose, mo lo!
Ohun Olorun w’ okan mi.

(Visited 484 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you