1. MO ha le tun duro
Laif’ ini mi toro?
Ki nmu okan kuro l’ aiye,
Ki ngba Olugbala?
2. Beko, mo ti tuba,
Nko le ba du lo pe,
Iku ife mu mi n’ ipa,
Mo gba Asegun mi.
3. Mo pe, sugbon mo ko
Gbogbo ohun aiye;
Baba alanu gba, ma mu
Se mi ni tire lai.
4. Wa, gba gbogb’ okan mi,
Ma si kuro nibe;
Mu aiduro okan mi ro,
Nipa ife Re nla.
5. Ki ife mi k’ o je
Lati mo ife Re;
Ki nko gbogbo ayo miran,
Ati ere sile.
(Visited 169 times, 1 visits today)