YBH 229

B’ AWON ara igbani

1. B’ AWON ara igbani
Ti f’ ayo ri ‘rawo na;
Bi nwon ti f’ inu didun
Tele ‘mole didan re;
Be, Oluwa Olore
Ni k’ a mu wa d’ odo Re.

2. Bi nwon ti fi ayo lo
Si ibuje eran na;
Ti nwon si wole nibe
F’ Eni t’ orun t’ aiye mbo;
Gege be ni k’ a ma yo
Lati wa s’ ile anu.

3. Bi nwon ti mu ore wa
Si ibuje eran na;
Be ni k’ awa ma f’ ayo
Mimo t’ ese ko baje
Mu ‘sura wa gbogbo wa
S’ odo Re, Jesu Oba.

4. Jesu mimo, pa wa mo,
L’ ona toro l’ ojojo;
‘Gbat’ ohun aiye ba pin,
M’ okan wa de ilu ti
‘Rawo ko ns’ amona mo;
‘Biti nwon now ogo Re.

5. Ni ‘lu orun mimo na,
Nwon ko wa imole mo;
‘Wo l’ Orun re ti ki wo;
‘Wo l’ ayo at’ ade re;
Nibe titi l’ ao ma ko
Halleluya s’ Oba wa.

(Visited 496 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you