1. OJO mefa t’ ise koja,
Okan t’ isimi si bere;
Pada okan mi wa ‘simi,
Yo s’ ojo t’ Oluwa busi.
2. Ki ero at’ ope wan de
Bi ebo turari s’orun
K’ o le fa inu didun wa
Ti kik’ awon t’ o ni l’ o mo.
3. Idake roro kun okan,
Eleri isimi ti mbo,
T’ oku fun ‘jo enia Re,
Opin lala at’ irora.
4. A f’ ayo wo ‘se Re, Oba;
Oniruru, ogbo, otun;
A yin O fun anu t’ o lo,
A si nreti eyi ti mbo.
5. F’ oni se ‘sin mimo jale.
Si se pelu inu didun,
Ojo ‘simi ‘ba ti dun to,
Niret’ eyi ti ko l’ opin.
(Visited 421 times, 1 visits today)