1. KABO ojo ‘simi
T’ o r’ ajinde Jesu;
Ma bowa s’ okan ti nsoji,
At’ oju ti nyo yi!
2. Oba pa sunmo wa,
Lati bo enia re;
Nihin l’ a le joko, k’ a ri,
K’ a fe, k ‘ a yin, k’ a sin.
3. Ojo kan nibiti
‘Wo, Oluwa mi ngbe,
O san j’ egbarun ojo lo
T’ a nje faji ese.
4. Okan mi fe f’ ayo
Duro n’ ipo bayi;
Ko si joko lati korin,
Tit’ aiye ailopin.
(Visited 350 times, 1 visits today)