YBH 28

OJO ‘simi at’ ayo

1. OJO ‘simi at’ ayo
Ojo inu didun,
Etutu fun wahala,
T’ o dara, t’ o si ndan!
L’ ori re, awon ‘lola
At’ otosi nkorin,
Pe, “Mimo, mimo, mimo,”
S’ Eni Metalokan.

2. L’ ori re ni did’ aiye
N’ imole ko ran si,
L’ ori re fun ‘gbala wa,
Jesu nde labe ‘le;
Ati nigbat’ O segun
O ran Emi wa ‘le,
Be l’ a rip e l’ ori re,
N’ imole mata se.

3. Loni fun gbogb’ alare,
Manna nwo lat’ orun;
Fere fadaka si npe,
Fun ipejo mimo;
Nibiti ihinrere
Gbe ntan ‘mole ogo,
At’ ibit’ omi iye
Gbe nsan omi tutu.

(Visited 1,697 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you