1. MO fe O n’gbagbogbo,
Oluwa Olore
Ko s’ ohun ti nfun ni
L’ alafia bi Tire
Mo fe O, a! mo fe O,
Ni wakati gbogbo;
Bukun mi Olugbala,
Mo wa s’ odo Re.
2. Mo fe O n’ gbagbogbo,
Duro ti mi,
Idanwo ko n’ ipa
Gbat’ O wa nitosi.
3. Mo fe O n’ gbagbogbo,
L’ ayo tab’ irora;
Yara wa ba mi gbe,
K’ aiye mi ma j’ asan.
4. Mo fe O n’gbagbogbo,
Ko mi ni ife Re;
K’ O je k’ileri Re
Se si mi li ara.
5. Mo fe O n’gbagbogbo,
Ologo julo;
Se mi n’ Tire toto,
Omo alabukun.
(Visited 2,674 times, 1 visits today)