YBH 271

IFE lo to bayi

1. IFE lo to bayi?
Ohun gbogbo pari,
O ti pari gbogbo ise
T’ O tori re w’ aiye.

2. Ohun ti Baba fe,
Ni Jesu ti se tan;
Wahala ati iya Re,
Ni Bibeli ti so.

3. Ko s’ ohun t’ a le se,
Ninu iya t’ O je,
‘Banuje on irora nla
Wo l’ okan lo sinsin.

4. L’ ori t’ a f’ egun de,
At’ okan Re mimo,
L’ o ko gbogbo ese wa lo,
K’ o ba le wo wa san.

5. Ife l’ o mu k’ o ku
Fun emi otosi:
O ko gbogbo ebi mi lo,
Jo je ki nro mo O.

6. Ati nigba aini,
Ati n’ite ‘dajo,
Jesu ododo Re nikan,
Ni igbeke mi.

7. Jo sise ninu mi,
Bi O ti nse fun mi,
Si je ki ife mi si O
Ma fi ore Re han

(Visited 432 times, 2 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you