YBH 272

MURA ebe, okan mi

1. MURA ebe, okan mi
Jesu nfe gb’ adura re;
O tip e k’ o gbadura,
Nitorina yio gbo.

2. Lodo Oba n’ iwo mbo,
Wa lopolopo ebe;
Be l’ ore-ofe Re po,
Ko s’ eni ti bere ju.

3. Mo t’ ibi eru bere,
Gba mi ni eru ese!
Ki eje t’O ta sile,
We ebi okan mi mu.

4. S’odo Re mo wa simi,
Oluwa gba aiya mi:
Nibe ni ki O joko,
Ma je Oba okan mi.

5. N’irin ajo mi l’aiye,
K’ ife Re ma tu mi n’nu;
Bi ore at’ oluso,
Mu mi d’opin irin mi.

6. F’ ohun mo ni se han mi,
Fun mi l’ otun ilera;
Mu mi wa ninu ‘gbagbo,
Mu mi ku b’enia Re.

(Visited 506 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you