1. GBA aiye mi, Oluwa,
Mo ya si mimo fun O;
Gba gbogbo akoko mi,
Ki nwon kun fun iyin Re.
2. Gba owo mi, k’ O si je
Kin ma lo fun ife Re;
Gba ese mi, k’ O si je
Ki nwon ma sare fun O.
3. Gba ohun mi, je kin ma
Korin f’ Oba mi titi;
Gba ete mi, je kin won
Ma jise fun O titi.
4. Gba wura. fadaka mi,
Okan nki o da duro;
Gba ogbon mi, Tire ni se,
Gege bi O ba ti fe.
5. Gba ‘fe mi, fi se Tire
Ki y’o tun je t’ emi mo
Gb’ okan mi, Tire ni se,
Ma gunwa nibe titi.
6. Gba ‘feran mi, Oluwa,
Mo fi gbogbo re fun O:
Gb’ emi papa: lat’ oni
Ki ‘m’ je Tire titi lai.
(Visited 3,983 times, 17 visits today)